Tuesday, 14 February 2017

Wisdom is very important - Ọgbọ́n ṣe pàtàkì, o ṣe kókó

For the Yorùbá, the importance of wisdom in our daily lives cannot be overemphasised…
Ọgbọ́n inú ọmọ ni yọ ọmọ lẹ̀nu
Ọ̀nà ọ̀fun ọ̀mọ̀rán ni ro ọ̀mọ̀rán lérò
Ọgbọ́n inú ọ̀lẹ ni ọ̀lẹ fi njẹun
Aṣiwèrè ènìyàn ni ko mọ àtiṣe ara rẹ
Bi a ko jiya ti o kun agbọ̀n
A ko le jore to kun inu ago
Igbó etílé on ẹ̀gbin
Àdàpọ̀ òwò on ìyà
Yàrá ajùmọ̀gbé mbi ekòló ninu
Ọgbọ́n ribiribi nla fi gba ọgbọ́n ribiribi
Ba a o ba ni ọgbọ́n ribiribi ninu,
A ko le kọ ògùn ribiribi
Bi a o ba kọ ògùn ribiribi
A ko le wo arun ribiribi
Bi a o ba wo arun ribiribi
A ko le gba owó ribiribi
Bi a o ba gba owó ribiribi
A ko le ri nkan ribiribi gbé ṣe
In English...
The wisdom of a child is his trouble
The throat of a diviner is his publicity agent
Lazy men live by their wisdom
Only fools do not know how to manage their affairs
If we do not bear suffering that will fill a basket
We will not receive kindness that will filI a cup
A forest near town collects rubbish
A partnership breeds suffering
A shared room breeds worms
Great wisdom is the key to getting even greater wisdom
If we don't have great wisdom
We can't learn strong medicine
If we don't learn strong medicine
We can't cure serious illness
If we can't cure serious illness,
We don't earn great wealth
If we don't earn great wealth
We can't do great things

No comments:

Post a Comment