Thursday 27 April 2017

Epistle of Ògbè Ọ̀yẹ̀kú verse 2….

Ògbè Ọ̀yẹ̀kú yẹ̀kẹ̀tẹ̀ a da fún Ọlọ́fìn tí ipò yẹ l’órí rẹ. Ifá ni ẹnìkan ní o wa lórí oyè yí tí a o pa n’ípò dà tí a o fi ẹni tí o wa ni ìkọ̀kọ̀ dípò rẹ. Ẹni ìkọ̀kọ̀ na ni gbogbo aráyé yio ma ra ọwọ́ sí tí wọn yio si ma júbà fún. 
Òrìṣà kan si ni yi tí gbogbo ilé ti ḿbọ ti wọn ko si bọ mọ́; igbó si kún bo ojúbọ rẹ; ki a tunṣe, ki a si ta màrìwò si ẹnu ọ̀nà rẹ.
Ẹni ikọkọ ti t’ọmọdé t’àgbà ti nfi ojú tinrin rẹ yio si di ẹni igbangba.
Adìẹ kan wa ni ile ẹniti o da Ifá yi, adìẹ na ni ọmọ l’ẹhin, ki a ko adìẹ na ati on ti ọmọ rẹ ki a fi ru ẹbọ.
Stout Ògbè Ọ̀yẹ̀kú was the one who cast Ifá for a king who had been dethroned. Ifá says there is someone who has a title, he will be removed from office and a person who stays in the corner will be chosen to fill his position. All people will rub their hands to the person of the corner and pay homage to him.
There is also a deity that was once worshipped by all the people of a house, but they do not worship him anymore and the forest has overgrown his altar. We should renovate the altar and tie palm fronds at its entrance. The person of the corner is someone at whom young children and old alike are sneering, but will leave his corner and come out into the open.
There is a hen at the house of the person for whom this figure was cast. This hen has chicks; we should take both the hen and it's young to make the sacrifice.

No comments:

Post a Comment