Thursday 27 April 2017

Epistle of Ọ̀yẹ̀kú Méjì...

Epistle of Ọ̀yẹ̀kú Méjì...
Ìwọ yẹkú, emi yẹkú
Ọ̀yẹ̀kú di méjì, o d'eji
A difá fun Kowa
A bù fún Tàmẹ̀dù
Níjọ́ ti Làkáṣègbé
N fi omi ojú sogbere ọmọ
Wọ́n ní ki i ṣe ti ìgbín
Ko dùbúlẹ̀ lai ni ìkarahun
Wọ́n ní ki i ṣe ti ọká
Ko dùbúlẹ̀ lai lóró inú
Wọ́n ní ki i ṣe ti ìrẹ̀
Ko dùbúlẹ̀ lai han gaaraga.
Wọ́n ni iran ọgà
Ki i rin lai ni igba aṣọ.
Wọ́n ni ko rúbọ
Ko ru eku méjì oluwere
Wọ́n ni ko ru ẹja méjì abiwẹ gbada
Wọ́n ni ko ru obidiẹ méjì abẹ̀dọ̀ lukẹlukẹ
Ewúrẹ́ méjì abamu rẹdẹrẹdẹ
Ẹinla méjì to fi iwo ṣoṣuka
O gbọ́ riru ẹbọ o ru.
O gbọ́ titu atukesu, o tu
O gbọ́ ikarara
Ẹbọ ha fun un.
Bi iyawo ti n ti ọwọ́ ala bọ osùn
Ni iyale n bi wẹ́rẹ́
Ijó ni n jo
Ayọ̀ ni n yọ
Ẹsẹ̀ to na
Ijó fa a
O ni bẹ ni àwọn awo oun
Ti n fi ẹnu rere pe ifa.
Ìwọ yẹkú, emi yẹkú
Ọ̀yẹ̀kú di meji
Gbogbo aye lo tu mi lara.
Translation...
I avoid death, you avoid death
Oyeku becomes two, it becomes two
Cast Ifa for Kowa
And also for Tamedu
On the day that Lakasegbe
Was crying due to infertility
It is unlike the snail
To sleep outside of its shell
It is unlike the viper
To sleep without its venom
It is unlike the cricket
To sleep without making chirping sound
No generation of chameleon
Moves without a box load of two hundred clothes
He was told to offer a sacrifice
Two swift-running rodents
Two giant fishes with large fins
Two huge hens
Two pregnant goats
Two deers with twisted horns
He agreed and offered the prescribed sacrifices
He paid attention to the needs of Esu
He heard ikarara, the sound of good fortune
His sacrifices were accepted
As his younger wife is rubbing her baby with camwood powder
The senior wife will be delivery here children safely
He began to dance
He began to rejoice
He stretched a leg
And dance ensues
He says that is exactly how his diviners
Give thanks and praise to Ifa
I avoided death, you avoided death
Oyeku becomes two
And the entire world makes me feel comfortable

No comments:

Post a Comment